Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13:9-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Ṣùgbọ́n Ṣọ́ọ̀lù ti a ń pè ni Pọ́ọ̀lù, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Ẹ́límù, ó sì wí pé,

10. “Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà-ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ Èṣù, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po?

11. Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí òòrùn ní sáà kan!”Lójúkan náà ìkunkùn àti òkùnkùn sí bò ó; ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ.

12. Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa.

13. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Páfòsì wọ́n wá sí Págà ni Pàmífílíà: Jòhánù sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerúsálémù.

Ìṣe Àwọn Àpósítélì 13