36. “Nítorí lẹ́yìn ìgbà ti Dáfídì ti sin ìran rẹ tan nípa Ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sùn, a sì tẹ́ ẹ ti àwọn baba rẹ̀, ara rẹ̀ sì rí ìdíbàjẹ́.
37. Ṣùgbọ́n ẹni tí Ọlọ́run jí dìde kò rí ìdíbàjẹ́
38. “Ǹjẹ́ kí ó yé yín, ará pé nípasẹ̀ Jésù yìí ni a ń wàásù ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ fún yín.
39. Nípa rẹ̀ ni a ń dá olúkúlùkù ẹni tí ó gbàgbọ́ láre kúrò nínú ohun gbogbo, tí a kò lè dá yín láre rẹ̀ nínú òfin Mósè.
40. Nítorí náà, ẹ kíyèsára, kí èyí tí a ti sọ nínú ìwé àwọn wòlíì má ṣe dé bá yín pé:
41. “ ‘Ẹ wò ó, ẹ̀yin ẹlẹ́gàn,kí ẹnu sì yà yín, kí a sì fẹ́ yín kù;nítorí èmi ń ṣe iṣẹ́ kan lọ́jọ́ yín,iṣẹ́ tí ẹ̀yin kò jẹ́ gbàgbọ́bí ẹnìkan tilẹ̀ ròyìn rẹ̀ fún yín.’ ”
42. Bí Pọ́ọ̀lù àti Bánábà sì ti ń jáde láti inú sínàgọ́gù, wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé kí a sọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí i fún wọn lọ́jọ́ ìsinmi tí ń bọ̀.