27. Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé, ó sì rí àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n péjọ.
28. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilé mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́.
29. Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi: ǹjẹ́ mo bèèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?”
30. Kọ̀nẹ́líù sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹ́sàn-án ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi.
31. Ó sì wí pé, ‘Kọ̀nélíù, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run.