Hósíà 8:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ísírẹ́lì ni wọ́n ti wá!Ère yìí—agbẹ́gilére ló ṣe éÀní ère Samáríà, ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́.

7. “Wọ́n gbin afẹ́fẹ́wọ́n sì ká ìjìIgi ọkà kò lórí,kò sì ní mú oúnjẹ wá.Bí ó bá tilẹ̀ ní ọkààwọn àlejò ni yóò jẹ.

8. A ti gbé Ísírẹ́lì mì,Báyìí, ó sì ti wà láàrin àwọn orílẹ̀ èdèbí ohun èlò tí kò wúlò.

Hósíà 8