Hósíà 6:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ẹ jẹ́ kí a mọ OlúwaẸ jẹ́ kí a tẹ̀ṣíwájú láti mọ̀ ọ́.Gẹ́gẹ́ bí oòrùn ṣe ń yọ,Yóò jáde;Yóò tọ̀ wá wá bí òjòbí òjò àkọ́rọ̀ ti ń bomirin ilẹ̀.”

4. “Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Éfúráímù?Kí ni èmi ó ṣe pẹ̀lú rẹ, Júdà?Ìfẹ́ rẹ dàbí ìkùùku òwúrọ̀bí ìrì ìdájí tí ó kọjá lọ kíákíá.

5. Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu miÌdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín

6. Nítorí pé mo fẹ́ àánú, kì í ṣe ẹbọ;àti ìmọ́ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.

Hósíà 6