4. “Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá,kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹ̀nìkéjìnítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbíàwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà
5. Ẹ ń ṣubú lọ́sàn-án àti lóruàwọn wòlíì yín sì ń ṣubú pẹ̀lúu yínÈmi ó pa ìyá rẹ run
6. Àwọn ènìyàn mi ń ṣègbé nítorí pé wọn kò ní ìmọ̀“Nítorí pé ẹ ti kọ ìmọ̀ sílẹ̀.Èmi náà kọ̀ yín ní àlùfáà mi;nítorí pé ẹ ti kọ òfìn Ọlọ́run yín sílẹ̀Èmi náà yóò gbàgbé àwọn ọmọ yín.
7. Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí ibẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi.Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú
8. Wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀sẹ̀ àwọn ènìyàn miWọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.
9. Yóò wá ṣe gẹ́gẹ́: bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà ríÈmi ó jẹ gbogbo wọn níyà nítorí ọ̀nà wọn.Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.
10. “Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó;Wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i,nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwasílẹ̀