Hósíà 12:3-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Láti inú oyun ni ó ti di arákùnrin rẹ̀ mú ni gìgísẹ̀,àti nípa ìpá rẹ̀ ó ni agbára pẹ̀lú Ọlọ́run

4. Ó bá ángẹ́lì ja ìjàkadì, ó sì borí rẹ̀Ó sunkún, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún ojú rere rẹ̀Ó bá Olúwa ní Bẹ́tẹ́lìÓ sì bá a sọ̀rọ̀ níbẹ̀,

5. àní Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun; Olúwa ni orúkọ ìrántí rẹ̀

6. Ṣùgbọ́n ìwọ́ gbọdọ̀ padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run rẹ̀;Di ìfẹ́ àti ìdájọ́ òdodo múkí ẹ sì dúró de Olúwa yín nígbà gbogbo.

7. Oníṣòwò ń lo òṣùnwọ̀n èkéÓ fẹ́ràn láti rẹ́nijẹ.

8. Éfúráímù gbéraga,“Èmi ní ìní fún ara mi, mo sì ti di ọlọ́rọ̀,pẹ̀lú gbogbo ọrọ̀ mi yìí, wọn kò le ká àìṣedéédéétàbí ẹ̀ṣẹ̀ kankan mọ́ mi lọ́wọ́”

9. “Èmi ni Olúwa Ọlọ́run rẹ;ẹni tí ó mu ọ jáde wá láti ilẹ̀ Éjíbítì;èmi yóò tún mú yín gbé nínú àgọ́bí i ọjọ́ àjọ mímọ́ wọ̀n ọn nì

10. Mo sọ fún àwọn wòlíì,mo fi ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ìran hàn wọ́nmo sì pa òwe láti ẹnu wòlíì wọn.”

11. Gílíádì ha burú bí?Àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ asán.Ǹjẹ́ wọ́n ń fi akọ màlúù rúbọ ní Gílígálì?Gbogbo pẹpẹ wọ́n sì dàbí ebènínú aporo oko.

Hósíà 12