12. Nígbà náà ni Sérúbábélì ọmọ Séítíélì, Jósúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà pẹ̀lú gbogbo ènìyàn ìyókù, gba ohùn Olúwa Ọlọ́run wọn gbọ́ àti ọ̀rọ̀ wòlíì Hágáì, nítorí Olúwa Ọlọ́run ni ó rán an. Àwọn ènìyàn sì bẹ̀rù Olúwa.
13. Nígbà náà ni Hágáì ìránṣẹ́ Olúwa ń jíṣẹ́ Olúwa fún àwọn ènìyàn pé, “Èmí wà pẹ̀lú yín,” ni Olúwa wí.
14. Nítorí náà, Olúwa ru ẹ̀mí Sérúbábẹ́lì ọmọ Séítélì sókè, olórí Júdà àti ẹ̀mí Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn,
15. ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì ọba Dáríúsì.