Hábákúkù 3:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Àdúrà wòlíì Hábákúkù gẹ́gẹ́ bí sígónótì.

2. Olúwa mo tí gbọ́ ohùn rẹ;ẹrú sì ba mi fún iṣẹ́ rẹ Olúwaṣọ wọn di ọ̀tún ní ọjọ́ ti wa,ní àkókò tiwa, jẹ́ kó di mímọ̀;ni ìbínú, rántí àánú.

3. Ọlọ́run yóò wa láti Témánì,Ibi mímọ́ jùlọ láti Òkè Páránìògo rẹ̀ sí bo àwọn ọ̀run,Ilé ayé sì kún fún ìyìn rẹ

4. Dídán rẹ ṣí dàbí ìmọ́lẹ̀;Ìmọ́lẹ̀ kọ-ṣàn-án láti ọwọ́ rẹ wá,níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.

5. Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ ni iwájú rẹ;ìyọnu ṣí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.

Hábákúkù 3