Hábákúkù 2:14-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nítorí tí ayé yóò kún fún ìmọ̀ ògo Olúwa,bí omi ṣe bo òkun.

15. “Ègbé ni fún ẹni tí ó fi ohun mímu fún aládùúgbò rẹ̀,tí ó sì fí ọtí-lílé rẹ̀ fún un, tí o sì jẹ́ kó mu àmupara,kí ìwọ kí ó ba lè wo ìhòòhò wọn

16. Ìtì jú yóò bò ọ́ dípò ògo, ìwọ náà mu pẹ̀lúkí ìhòòhò rẹ kí ó lè hàn,aago ọwọ́ ọ̀tún Olúwa, yóò yípadà sí ọ,ìtìjú yóò sì bo ògo rẹ.

17. Nítorí ìwà-ipá tí ó tí hù sí Lébánónì yóò bò ọ́,àti ìparun àwọn ẹranko yóò dẹ́rùbà ọ́.Nítorí ìwọ tí ta ẹ̀jẹ̀ ènìyàn sílẹ̀;ìwọ tí pa ilẹ̀ náà àti ìlú ńlá run àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú rẹ̀.

18. “Èrè kí ni òrìṣà ni, tí oníṣọ̀nà rẹ̀ fi gbẹ́ ẹ,ère dídá àti olùkọ́ èké?Nítorí ti ẹni ti ó dá a gbẹ́kẹ̀ rẹ̀ lé ohun tí ó fúnrarẹ̀ dá;ó sì mọ ère tí kò le fọhùn.

Hábákúkù 2