Gálátíà 5:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ǹjẹ́ àwọn iṣẹ́ tí ara farahàn, tíí ṣe wọ̀nyí; panṣágà, àgbèrè, ìwà èérí, wọ̀bìà,

20. Ìbọ̀rìṣà, oṣó, ìkórira, ìjà, ìlara, ìbínú, ìmọtara-ẹni nìkan, ìyapa, ẹ̀kọ́-òdí.

21. Àrankan, ìpànìyàn, ìmutípara, ìréde-òru, àti irú ìwọ̀nyí; àwọn ohun tí mo ń wí fún yín tẹ́lẹ̀, gẹ́gẹ́ bí mo ti wí fún yín tẹ́lẹ̀ rí pé, àwọn tí ń ṣe nǹkan báwọ̀nyí kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run.

22. Ṣùgbọ́n èèso ti Ẹ̀mí ni ìfẹ́, ayọ̀, àlàáfíà, ìpamọ́ra, ìwàpẹ̀lẹ́, ìṣoore, ìgbàgbọ́,

Gálátíà 5