Gálátíà 3:15-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ará, èmi ń ṣọ̀rọ̀ bí ènìyàn: bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé májẹ̀mú ènìyàn ni, ṣùgbọ́n bí a ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀, kò sí ẹni tí ó lè sọ ọ́ di asán, tàbí tí ó lè fi kún un mọ́.

16. Ǹjẹ́ fún Ábúráhámù àti fún irú ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Òun kò ṣe wí pé, “Àti fún irú-ọmọ rẹ̀,” èyí tí í ṣe Kírísítì.

17. Èyí tí mò ń wí ni pé: Májẹ̀mu tí Ọlọ́run ti fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ níṣáájú, òfin ti ó dé lẹ́yìn ọgbọ̀n-lé-nírinwó ọdún kò lè sọ ọ́ di asán, tí à bá fi mú ìlérí náà di aláìlágbára.

18. Nítorí bí ìjogún náà bá ṣe ti òfin kì í ṣe ti ìlérí mọ́: ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fi í fún Ábúráhámù nípa ìlérí.

Gálátíà 3