Fílímónì 1:22-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Ó ku ohun kan: Ṣe ìtọ́jú ìyara àlejò rẹ sílẹ̀ fún mi, nítorí mo ní ìgbàgbọ́ pé a óò tú mi sílẹ̀ fún yín ní ìdáhùn sí àdúrà yín.

23. Ẹ́páfírà, òǹdè ẹlẹgbẹ́ mi nínú Kírísítì Jésù kí ọ.

24. Máàkù kí ọ pẹ̀lú Ańsíbákù, Dẹ́mà àti Lúùkù, àwọn alábàáṣiṣẹ́ mi.

25. Kí Oore-ọ̀fẹ́ Jésù Kírísítì Olúwa wa wà pẹ̀lú ẹ̀mí yín.

Fílímónì 1