Ẹ́sítà 9:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà, àwọn Júù pa ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta ọkùnrin run

7. Wọ́n sì tún pa parisánídátà, Dálífónì, Ásípátà,

8. Pórátà, Ádálíyà, Árídátà,

9. Parimásítà, Áríṣáyì, Árídáyì àti Fáíṣátà,

10. Àwọn ọmọkùnrin mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tí wọ́n jẹ́ ọmọ Hámánì, ọmọ Hámédátà, ọ̀ta àwọn Júù. Ṣùgbọ́n wọn kò fi ọwọ́ ọ wọn lé ìkógún un wọn.

11. Ní ọjọ́ náà gan-an ni a mú iye àwọn tí a pa ní ilé ìṣọ́ ti Ṣúṣà wá fún ọba.

Ẹ́sítà 9