2. Nígbà tí ó rí ayaba Ẹ́sítà tí ó dúró nínú àgbàlá, inú un rẹ̀ yọ́ síi, ó sì na ọ̀pá aládé wúrà ọwọ́ọ rẹ̀ sí i. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ́sítà ṣe ṣún mọ́ ọn ó sì fi ọwọ́ kan orí ọ̀pá náà.
3. Nígbà náà ni ọba béèrè pé, “kí ni ó dé, ayaba Ẹ́sítà? Kí ni o fẹ́? Bí ó tilẹ̀ ṣe títí dé ìdajìn mi ìjọba àní, a ó fi fún ọ.”
4. Ẹ́sítà sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí ọba, pẹ̀lúu Hámánì, wá lónìí sí ibi àṣè tí èmi ti pèṣè fún-un.”
5. Ọba sì wí pé, “ẹ mú Hámánì wá kíákíá,” “nítorí kí a lè ṣe ohun tí Ẹ́sítà béèrè fún un.”Bẹ́ẹ̀ ni ọba àti Hámánì lọ sí ibi àsè tí Ẹ́sítà ti pèsè.
6. Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì, ọba tún béèrè lọ́wọ́ Ésítà, “Báyìí pẹ́: kí ni ẹ̀bẹ̀ rẹ? A ó sì fi fún ọ. Kí ni ìwọ ń béèrè fún? Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ ìdajì ìjọbaa mi, a ó fi fún ọ.”