19. Nígbà tí àwọn wúndíá tún péjọ ní ìgbà kejì, Módékáì jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọbà.
20. Ṣùgbọ́n Ẹ́sítà pa àṣírí ìdílé e rẹ̀ àti ibi tí ó ti wá mọ́gẹ́gẹ́ bí Módékáì ṣe sọ fún un pé kí ó ṣe, nítorí tí ó ń tèlé àṣẹ tí Módékáì fún-un gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń ṣe nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Módékáì.
21. Ní àsìkò tí Módékáì jókòó sí ẹnu ọ̀nà ọba, Bígítanà àti Térésì, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n máa ń ṣọ́ ẹnu ọ̀nà, wọ́n bínú, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa ọba Sérísésì.
22. Ṣùgbọ́n Módékáì sì mọ̀ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ̀ fún ayaba Ẹ́sítà, Ẹ́sítà sì sọ fún ọba, wọ́n sì fi ọlá fún Módékáì.
23. Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀rọ̀ náà tí ó sì já sí òtítọ́, a sì ṣo àwọn ìjòyè méjèèjì náà kọ́. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a kọ sínú ìwé ìtàn ní iwáju ọba.