17. Fún yíya ilé Ọlọ́run yìí sí mímọ́, wọ́n pa ọgọ́rùn-ún akọ màlúù (100), ọgọ́rùn-ún méjì àgbò (200) àti ọgọ́run mẹ́rin akọ ọ̀dọ́ àgùntàn (400), àti gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Ísírẹ́lì, obúkọ méjìlá (12), ọ̀kọ̀ọ̀kan fún olúkúlùkù àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì.
18. Wọ́n sì fi àwọn àlùfáà sí àwọn ìpínsọ́wọ́ àti àwọn Léfì sì ẹgbẹẹgbẹ wọn fún ìsin ti Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù, gẹ́gẹ́ bí ohun tí a kọ sínú ìwé Mósè.
19. Ní ọjọ́ kẹrìnlá ti oṣù Nísàn (oṣù kẹrin), àwọn tí a kó ní ìgbèkùn ṣe ayẹyẹ àjọ ìrékọjá.
20. Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Léfì pa ọ̀dọ́ àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn.