1. Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, àwọn ènìyàn péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní Jérúsálẹ́mù.
2. Nígbà náà ni Jéṣúà ọmọ Jósádákì àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mósè ènìyàn Ọlọ́run
3. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká ń bà wọ́n ṣíbẹ̀, wọ́n kọ́ pẹpẹ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rú ọrẹ sísun lórí rẹ̀ sí Olúwa, ọrẹ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́.
4. Nígbà náà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ, wọ́n ṣe àpèjọ àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú iye ọrẹ sísun tí a fi lélẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.
5. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti-gbà-dé-gbà, ẹbọ oṣù tuntun àti gbogbo àwọn ẹbọ fún gbogbo àpèjẹ tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti àwọn tí a mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá fún Olúwa.
6. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní rú ọrẹ sísun sí Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ì tí ì fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀.