Ẹkún Jeremáyà 5:19-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

19. Ìwọ, Olúwa, jọba títí láé;ìjọba rẹ dúró láti ìran kan dé ìran mìíràn.

20. Kí ló dé tí o n gbàgbé wa ní gbogbo ìgbà?Kí ló dé tí o fi kọ̀ wá sílẹ̀ fún ọjọ́ pípẹ́?

21. Mú wa padà sí ọ̀dọ̀ rẹ, Olúwa, kí àwa kí ó le padà;mú ọjọ́ wa di tuntun bí ìgbà a nì

22. Àyàfi tí o bá ti kọ̀ wá sílẹ̀ pátápátátí ìbínú rẹ sí wa sì kọjá ìwọ̀n.

Ẹkún Jeremáyà 5