Ẹkún Jeremáyà 3:57-62 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

57. O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́,o sì wí pé, “Má se bẹ̀rù.”

58. Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò,o ra ẹ̀mí mi padà.

59. O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí miGbé ẹjọ́ mi ró!

60. Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn,gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.

61. Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọnàti ìmọ̀ búburú wọn sí mi—

62. Ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọsí mi ní gbogbo ọjọ́.

Ẹkún Jeremáyà 3