Ẹkún Jeremáyà 3:45-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

45. Ó ti sọ wá di èérí àti ààtànláàrin orílẹ̀ èdè gbogbo.

46. “Gbogbo àwọn ọ̀tá wa ti la ẹnu wọngbòòrò sí wa.

47. Àwa ti jìyà àti ìparun,nínú ìbẹ̀rù àti ewu.”

48. Omijé ń ṣàn ní ojú mi bí odònítorí a pa àwọn ènìyàn mi run.

49. Ojú mi kò dá fún omijé,láì sinmi,

50. títí ìgbà tí Olúwa síjú wolẹ̀láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.

Ẹkún Jeremáyà 3