Ẹkún Jeremáyà 3:28-33 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

28. Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́jẹ́,nítorí Olúwa ti fi fún un.

29. Jẹ́ kí ó bò ojú rẹ̀ sínú eruku—ìrètí sì lè wà.

30. Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a,sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.

31. Ènìyàn kò di ìtanùlọ́dọ̀ Olúwa títí láé.

32. Lóòtọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn,nítorí náà títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.

33. Nítorí kò mọ̀ọ́mọ̀ mú ìpọ́njú wátàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.

Ẹkún Jeremáyà 3