Ẹkún Jeremáyà 3:25-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,sí àwọn tí ó ń wá a.

26. Ó dára kí a ní ṣùúrùfún ìgbàlà Olúwa.

27. Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgànígbà tí ó wà ní èwe.

28. Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́jẹ́,nítorí Olúwa ti fi fún un.

29. Jẹ́ kí ó bò ojú rẹ̀ sínú eruku—ìrètí sì lè wà.

30. Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a,sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.

31. Ènìyàn kò di ìtanùlọ́dọ̀ Olúwa títí láé.

Ẹkún Jeremáyà 3