Ékísódù 35:5-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Láti inú ohun tí ẹ ni ni kí ẹ ti mú ọrẹ fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ọ́ bá fẹ́ ni kí ó mú ọrẹ fún Olúwa ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ;

6. aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára; àti irun ewúrẹ́;

7. awọ àgbò tí a kùn ní pupa àti awọ màlúù; odò igi kaṣíá;

8. òróró ólífì fún títan iná; olóòórùn fún òróró ìtasórí, àti fún tùràrí dídùn;

9. Òkúta óníkìsì àti òkúta tí a tò sí ẹ̀wù èfòdì àti igbáàyà.

Ékísódù 35