Ékísódù 34:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Má a sọ́ra kí o má ba à bá àwọn ti ó n gbé ilẹ náà tí ìwọ ń lọ dá májẹ̀mú, nítorí wọn yóò jẹ́ ìdíwọ́ láàrin rẹ.

13. Wó pẹpẹ wọn lulẹ̀, fọ́ òkúta mímọ́ wọn, kí o sì gé òpó Ásérè wọn. (Ère òrìsà wọn).

14. Ẹ má se sin ọlọ́rùn mìíràn, nítorí Olúwa, orúkọ ẹni ti ń jẹ́ òjòwú, Ọlọ́run owú ni.

15. “Má a sọ́ra kí ẹ má se bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú; nígbà tí wọ́n bá ń se àgbérè tọ òrìsà wọn, tí wọ́n sì rúbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn.

Ékísódù 34