Ékísódù 30:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Olúkúlùkù ẹrù tí ó bá kọjá lọ sọ́dọ̀ àwọn tí a ti kà yóò san ìdajì sékéli (gíráámù mẹ́fà), gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́, èyí tí ó wọn ogún gérà. Ìdajì sékélì yìí ní ọrẹ fún Olúwa.

14. Gbogbo àwọn tí ó bá kọjá sínú àwọn tí a kà láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, ni yóò fi ọrẹ fún Olúwa.

15. Àwọn olówó kì yóò san ju ìdajì sékélì lọ, àwọn talákà kò sì gbọdọ̀ dín ní ìdajì sékélì nígbà tí ẹ̀yin bá mú ọrẹ wá fún Olúwa láti se ètùtù fún ọkàn yín.

Ékísódù 30