Ékísódù 29:34-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Bí ohun kan nínú ẹran àgbò ìyàsímímọ́ tàbí nínú àkàrà náà bá kù di òwúrọ̀, nígbà náà ni kí ìwọ fi iná sun wọn. A kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, nítorí mímọ́ ni.

35. “Bàyìí ni ìwọ yóò sìṣe fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ bí ohun gbogbo ti mo paláṣẹ fún ọ, ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi yà wọ́n sí mímọ́.

36. Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù. Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún-un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́.

37. Ní ọjọ́ méje ni ìwọ yóò ṣe ètùtù sí pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì sọ ọ́ di mímọ́. Nígbà náà ni pẹpẹ náà yóò jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohúnkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn-án yóò jẹ́ mímọ́.

38. “Èyí ni ìwọ yóò máa fi rúbọ ní orí pẹpẹ náà: Òdọ́ àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé.

Ékísódù 29