Ékísódù 28:33-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Ṣe pómégánátè ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò àti ti òdòdó yí ìsẹ́ti ọ̀já àmùrè náà ká, pẹ̀lú aago wúrà láàrin wọn.

34. Àwọn aago wúrà àti àwọn pómégánátè ni kí ó yí ìsẹ́tí ọ̀já àmùrè náà ká.

35. Árónì gbọdọ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí o bá ń sisẹ́. A ó sì máa gbọ́ ìró àwọn agogo nígbà tí ó bá ń wọ ibi mímọ́ níwájú Olúwa àti nígbà tí ó bá ń jáde bọ̀, kí ó má ba à kú.

36. “Ìwọ yóò sì ṣe àwo kìkì wúrà, ìwọ yóò sì fín sára rẹ̀ bí, fífín èdìdì àmì pé: ‘Mímọ́ sí Olúwa.’

37. Ìwọ yóò fi ọ̀já aláró sára rẹ̀ ìwọ yóò sì so ó mọ́ fìlà náà; kí ó sì wà níwájú fìlà náà.

Ékísódù 28