Ékísódù 28:30-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

30. Bákan náà ìwọ yóò sì mu Úrímù àti Tímímù sínú ìgbàyà, kí wọn kí ó wà ní ọkàn Árónì nígbàkúgbà tí ó bá ń wólẹ̀ níwájú Olúwa. Árónì yóò sì máa ru ohun ti a ń fi se ìpinu fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ọkàn rẹ̀ nígbàgbogbo níwájú Olúwa.

31. “Ìwọ yóò sìṣe aṣọ ìgúnwà ẹ̀wù éfódì náà ní kìkì aṣọ aláró,

32. pẹ̀lú ojú ọrùn kí ó wà láàrin rẹ̀ fún orí. Kí iṣẹ́ ọ̀nà wà létí rẹ̀ bí ìsẹ́tí yí i ká bí agbádá, kí ó má ba à ya.

Ékísódù 28