14. Àti okùn ẹ̀wọ̀n méjì ti kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bí ọ̀já àmùrè kí o sì so ẹ̀wọ̀n náà mọ́ ojú ìdè náà.
15. “Ìwọ yóò fi iṣẹ́ ọgbọ́n ṣe ìgbàyà fún ìpinu iṣẹ́ ọnà gbẹ́nàgbẹ́nà. Ìwọ yóò ṣe é bí ẹ̀wù èfòdì ti wúrà, ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn wíwẹ́ dáradára.
16. Kí ìhà mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ se déédé—kí ó jẹ́ ìwọ̀n ṣẹ́ńtímítà méjìlélógún ní gíga àti ìwọ̀n ṣẹ̀ńtímítà méjìlélógun (22 centimeters) ní fífẹ̀ kí o sì ṣe é ní ìsẹ́po méjì.
17. Nígbà náà ni ìwọ yóò de òkúta iyebíye mẹ́rin sára ẹṣẹ̀ rẹ̀. Ní ẹṣẹ̀ àkọ́kọ́ ni kí rúbì, tópásì àti bérílì wà;
18. ní ẹṣẹ̀ kejì émérálídì, sáfírù, àti díámóńdì;
19. ní ẹṣẹ̀ kẹta, lígúrè, ágátè, àti ámétísítì;
20. ní ẹṣẹ̀ kẹrin, bérílù, àti óníkísì àti Jásípérì. A ó sì tò wọ́n sí ojú wúrà ní dìde wọn.
21. Òkúta méjìlá (12) yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì olúkúlùkù èdìdì àmì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.