Ékísódù 25:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Gẹ́gẹ́ bí gbogbo èyí ti mo fi hàn ọ́, nípa àpẹẹrẹ àgọ́, àti àpẹẹrẹ gbogbo ohun èlò inú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó sì ṣe é.

10. “Kí wọn kí ó fi igi kasíà ṣe àpótí, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀, kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀.

11. Bo orí rẹ̀ pẹ̀lú ojúlówó wúrà, bò ó ni inú àti ìta kí o sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká.

12. Ṣe òrùka wúrà mẹ́rin fún un. Kí o sì so wọ́n mọ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì.

13. Fi igi kaṣíà ṣe òpó mẹ́rin, kí o sì fi wúrà bò ó.

14. Fi òpó náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí náà láti fi gbé e.

15. Òpó náà yóò wá nínú òrùka lára àpótí ẹ̀rí; a ko ní yọ wọ́n kúrò.

Ékísódù 25