31. “Mú ojúlówó wúrà, lù ú dáradára, kí o sì fi ṣe ọ̀pá fìtílà, ìsàlẹ̀ àti apá rẹ̀, kọ́ọ̀bù rẹ̀ ti ó dàbí òdòdó, ìṣọ àti ìtànná rẹ̀ yóò jẹ́ ara kan náà pẹ̀lú rẹ̀.
32. Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì.
33. Kọ́ọ̀bù mẹ́ta tí a se bí òdòdó alímọ́ńdì tí ó sọ tí ó sì tanná ni yóò wà ni apá kan, mẹ́ta yóò sì wà ní apá kejì, àti bẹ́ẹ̀ fún àwọn ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà tí ó jáde lára ọ̀pá fìtílà.
34. Ní ara ọ̀pá fìtílà ni kọ́ọ̀bù mẹ́rin ti a se gẹ́gẹ́ bí òdòdó alímọńdì ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà.