10. “Kí wọn kí ó fi igi kasíà ṣe àpótí, kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀, kí fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀.
11. Bo orí rẹ̀ pẹ̀lú ojúlówó wúrà, bò ó ni inú àti ìta kí o sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká.
12. Ṣe òrùka wúrà mẹ́rin fún un. Kí o sì so wọ́n mọ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì.
13. Fi igi kaṣíà ṣe òpó mẹ́rin, kí o sì fi wúrà bò ó.
14. Fi òpó náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí náà láti fi gbé e.
15. Òpó náà yóò wá nínú òrùka lára àpótí ẹ̀rí; a ko ní yọ wọ́n kúrò.
16. Nígbà náà ni ìwọ yóò fi ẹ̀rí ti èmi yóò fi fún ọ sínú àpótí náà.
17. “Ojúlówó wúrà ni kí o fi se ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan àti ààbọ̀ ní fífẹ̀.
18. Fi wúrà tí a lù se kérúbù méjì sí igun ìtẹ́-àánú.
19. Ṣe kérúbù kan sí igun kìn-ín-ní àti kérúbù kejì sí igun kejì kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì.