Ékísódù 22:17-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Bí baba ọmọbìnrin náà bá kọ̀ jálẹ̀ láti fi fún un ní aya, ó ni láti san owó tó tó owó orí rẹ̀, fún fí fẹ́ ẹ ní wúndíá.

18. “Má ṣe jẹ́ kí àjẹ́ kí ó wà láàyè.

19. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá bá ẹranko lopọ̀ ní a ó pa.

20. “Ẹnikẹ́ni ti ó bá rúbọ sí òrìṣà yàtọ̀ sí Olúwa nìkan, ni a ó yà sọ́tọ̀ fún ìparun.

21. “Ẹ má ṣe fi ìyà jẹ àlejò tàbí ni wọ́n lára, nítorí ìwọ pẹ̀lú ti jẹ́ àlejò ni ilẹ̀ Éjíbítì rí.

Ékísódù 22