22. “Bí àwọn ènìyàn ti ń jà bá pa aboyún lára, tí aboyún náà bá bimọ láìpé ọjọ́, ṣùgbọ́n ti kò sí aburú mìíràn mọ́ lẹ́yìn rẹ̀, ẹni ti ó fa ìpalára yìí yóò san iyekíye ti ọkọ aboyún náà bá béèrè fún, bí ilé ẹjọ́ bá se gbà láàyè gẹ́gẹ́ bí owó ìtanràn.
23. Ṣùgbọ́n bí ìpalára náà bá yọrí sí ikú aboyún náà, pípa ni a ó pa ẹni ti ó fa ikú aboyún náà.
24. Ojú fún ojú, eyín fún eyín, ọwọ́ fún ọwọ́, ẹṣẹ̀ fún ẹṣẹ̀,
25. ìjóná fún ìjóná, ọgbẹ́ fún ọgbẹ́, ìnà fún ìnà.
26. “Bí ọkùnrin kan bá lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ní ojú, ti ojú náà sì fọ́, ó ni láti jẹ́ kí ẹrú náà lọ ní òmìnira fún ìtanràn ojú rẹ̀ ti ó fọ́.
27. Bí ó bá sì lu ẹrúkùnrin tàbí ẹrúbìnrin rẹ̀ ti eyín rẹ̀ fi ká, ó ni láti jẹ́ kí ó lọ ní òmìnira ni ìtanran fún eyín rẹ̀ tí ó ká.
28. “Bí akọ màlúù bá kan ọkùnrin tàbí obìnrin kan pa, a ó sọ akọ màlúù náà ní òkúta pa, a kò sì gbọdọ̀ jẹ ẹran rẹ̀. Ṣùgbọ́n a kò ní dá ẹni tí ó ni akọ màlúù náà lẹ́bi, ọrùn rẹ̀ yóò sì mọ́.