Ékísódù 21:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. “Wọ̀nyí ni àwọn òfin tí ìwọ yóò gbé sí iwájú wọn:

2. “Bí ìwọ bá yá ọkùnrin Hébérù ní ìwẹ̀fà, òun yóò sìn ọ́ fún ọdún Mẹ́fà. Ṣùgbọ́n ní ọdún keje, òun yóò lọ ni òmìnira láìsan ohunkóhun padà.

3. Bí ó bá wá ní òun nìkan òun nìkan náà ni yóò padà lọ ní òmìnira; ṣùgbọ́n tí ó bá mú ìyàwó wá, ó ní láti mú ìyàwó rẹ̀ padà lọ.

Ékísódù 21