Lẹ́yìn ìgbà pípẹ́, ọba Éjíbítì kú. Àwọn ará Ísírẹ́lì ń kérora ní oko ẹrú wọn, wọ́n ń ké fún ìrànlọ́wọ́ nítorí oko ẹrú tí wọ́n wà, igbe wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.