14. Ọkùnrin náà sì dáhùn pé “Ta ni ó fi ọ́ jẹ olórí àti onídájọ́ lórí wa? Ṣé o fẹ́ pa mí bí o ṣe pa ará Éjíbítì?” Nígbà náà ni ẹ̀rù ba Mósè, ó rò nínú ara rẹ̀ pé “ó ní láti jẹ́ wí pé ohun tí mo ṣe yìí ti di mímọ̀.”
15. Nígbà ti Fáráò sì gbọ́ nípa èyí, ó wá ọ̀nà láti pa Mósè, ṣùgbọ́n Mósè sá kúrò ní àrọ́wọ́tó o Fáráò, ó lọ sí Mídíánì láti máa gbé, nígbà tí ó dé bẹ̀, ó jókòó ni ẹ̀bá a kànga kan.
16. Ó sì ṣe, àlùfáà Mídíánì kan ni àwọn ọmọbìnrin méje, wọn sì wá láti pọn omi kún ọpọ́n ìmumi fún ẹran ọ̀sìn baba wọn.
17. Àwọn darandaran kán wá, wọ́n sì lé wọn sẹ́yìn, ṣùgbọ́n Mósè dìde láti gbà wọ́n sílẹ̀ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ẹran wọn ní omi.
18. Nígbà ti àwọn ọmọbìnrin náà padà dé ọ̀dọ̀ Rúẹ́lì baba wọn, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé “Èéṣe tí ẹ̀yin fi tètè dé ni òní?”
19. Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ará Éjíbítì kan ni ó gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn darandaran, ó tilẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fa omi àti láti fún agbo ẹran ní omi.”