10. Olúwa sì wí fún Mósè pé, “Tọ àwọn ènìyàn lọ kí o sì yà wọ́n sí mímọ́ ni òní àti ni ọ̀la. Jẹ́ kí wọn kí ó fọ aṣọ wọn.
11. Kí wọn kí ó sì múra di ọjọ́ kẹ́ta, nítorí ni ọjọ́ náà ni Olúwa yóò sọ̀kalẹ̀ sí orí òkè Ṣínáì ni ojú gbogbo àwọn ènìyàn.
12. Kí ìwọ kí ó se ààlà fún àwọn ènìyàn, ibi tí wọn lè dé dúró, kí ìwọ kí ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ ṣọ́ra! Ẹ má ṣe gun orí òkè lọ, kí ẹ máa tilẹ̀ fi ọwọ́ kan etí ààlà rẹ̀; ẹnikẹ́ni tí ó bá fi ọwọ́ kan òkè náà yóò kú:
13. Ọwọ́kọ́wọ́ kò gbọdọ̀ kàn án, ẹni tí ó fi ọwọ́ kan òkè náà a ó sọ ọ́ ní òkúta tàbí kí a ta a ní ọfà, ìbá à ṣe ènìyàn tàbí ẹranko: Òun kì yóò wà láàyè.’ Nígbà ti ìpè bá dún nìkan ni kí wọn ó gun òkè wá.”
14. Mósè sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà wá sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn, ó yà wọ́n sí mímọ́, wọ́n sì fọ aṣọ wọn.
15. Ó sì sọ fún àwọn ènìyàn pé, “Ẹ múra sílẹ̀ di ọjọ́ kẹta; Ẹ má ṣe bá aya yín lòpọ̀.”