1. Gbogbo ìjọ ènìyàn Ísírẹ́lì si gbéra láti jáde kúrò láti ihà Sínì wọ́n ń lọ láti ibi kan de ibi kan gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Wọ́n pàgọ́ sí Réfídímù Ṣugbọ́n kò sí omi fún àwọn ènìyàn láti mú.
2. Àwọn ènìyàn sì sọ̀ fún Mósè, wọ́n wí pé, “Fún wa ni omi mu.”Mósè dá wọn lóhùn wí pé, “Èéṣe ti ẹ̀yin fi ń bá mi jà? Èése ti ẹ̀yin fi ń dán Olúwa wò?”
3. Ṣùgbọ́n òùngbẹ ń gbẹ àwọn ènìyàn, wọ́n sì ń kùn sí Mósè, wọ́n wí pé, “Èéṣe tí ìwọ fi mú wa jáde kúrò ní Éjíbítì láti mú kí òùngbẹ pa àwa, àwọn ọmọ wa àti ohun ọ̀sìn wa ku fún òùngbẹ.”