Ékísódù 16:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà tí ìrì tí ó sẹ̀ bo ilẹ̀ ti lọ, kíyèsí i, ohun tí ó dì, tí ó sì ń yooru bí i yìnyín wà lórí ilẹ̀.

15. Nígbà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rí i, wọ́n bi ara wọn léèrè pé, “Kí ni èyí?” Nítorí pé wọn kò mọ ohun tí i se.Mósè sì wí fún wọn pé, “Èyí ni oúnjẹ tí Olúwa fi fún un yín láti jẹ.

16. Èyí ni ohun tí Olúwa ti pàṣẹ: ‘Kí olúklùkù máa kó èyí ti ó tó fún un láti jẹ. Ẹ mú òṣùnwọ̀n ómérì kan (bí i líta méjì) fún ẹnikọ̀ọ̀kan ti ó wà nínú àgọ́ yín.’ ”

Ékísódù 16