Ékísódù 15:3-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ologun ni Olúwa, Olúwa ni orúkọ rẹ,

4. Kẹ̀kẹ́-ogun Fáráò àti ogun rẹ̀ni ó mú wọ inú òkun.Àwọn ọmọ ogun Fáráò tó jáfáfá jùlọni ó rì sínú òkun pupa.

5. Ibú omi bò wọ́n mọ́lẹ̀;Wọ́n sì rì sí ìsàlẹ̀ omi òkun bí òkúta.

6. “Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,pọ̀ ní agbára.Ọwọ́ ọ̀tún rẹ, Olúwa,fọ́ àwọn ọ̀ta túútúú.

7. Nínú agbára ńlá rẹ ti ó tóbiìwọ bi àwọn ti ó dìde sí ọ ṣubú.Ìwọ rán ìbínú gbígbóná rẹ;Tí ó run wọ́n bí ìgémọ́lẹ̀ ìdí koríko

Ékísódù 15