18. Olúwa yóò jọbaláé àti láéláé.”
19. Nígbà ti ẹsin Fáráò, kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn ẹlẹ́sin rẹ̀ wọ inú òkun, Olúwa mú kí omi òkun padà bò wọ́n mọ́lẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ la òkun kọjá.
20. Míríámù wòlíì obìnrin, arábìnrin Árónì, mú ohun èlò orin ni ọwọ́ rẹ̀, àwọn obìnrin ti ó tẹ̀lé pẹ̀lú mú ohun èlò orin wọ́n sì ń jó.
21. Míríámà kọrin sí wọn báyìí pé:“Ẹ kọrin sí OlúwaNítorí òun ni ológo jùlọẸṣin àti ẹni tí ó gùn únNi òun bi subú sínú òkun.”
22. Nígbà náà ni Mósè ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì jáde láti òkun pupa lọ sínú aṣálẹ̀ Ṣúrì. Wọ́n lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ijù náà, wọn kò sì rí omi.
23. Nígbà tí wọ́n dé Márà, wọn kò lè mu omi Márà nítorí omi náà korò (Nítorí náà ni a ṣe pe ibẹ̀ ni Márà: ibi ìkorò).