Ékísódù 13:21-22 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

21. Olúwa sì ń lọ níwájú wọn, nínú òpó ìkùùkuu ní ọ̀san láti máa ṣe amọ̀nà wọn àti ní òru nínú òpó iná láti máa tan ìmọ́lẹ̀ fún wọn, kí wọn lè máa lọ nínú ìrìnàjò wọn ní tọ̀sán tòru.

22. Ìkùùku náà kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ní ọ̀sán, bẹ́ẹ̀ ni, òpó iná kò kúrò ní ààyè rẹ̀ ni òru, ní iwájú àwọn ènìyàn náà.

Ékísódù 13