24. “Ẹ pa ìlànà yìí mọ́ gẹ́gẹ́ bí ohun tí ẹ ó máa ṣe títí ayérayé láàrin yín àti àwọn ìran yín.
25. Nígbà tí ẹ̀yin bá de ilẹ̀ tí Olúwa yóò fi fún un yín bí òun ti ṣe ìlérí, ẹ máa kíyèsí àjọ yìí.
26. Ní ìgbà tí àwọn ọmọ yín bá béèrè lọ́wọ́ yín, ‘Kí ni ohun tí àjọ yìí túmọ̀ sí fún un yín?’
27. Ẹ sọ fún wọn ni ìgbà náà, ‘Ẹbọ ìrékọjá sí Olúwa ni, ẹni tí ó rékọjá ilé e wa ni ìgbà tí ó kọlu àwọn ara Éjíbítì. Tí ó si da wa sí nígbà ti ó pa àwọn ara Éjíbítì.’ ” Àwọn ènìyàn sì tẹríba láti sìn.
28. Àwọn Ísírẹ́lì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè àti Árónì.