9. Olúwa ti sọ fún Mósè pé, “Fáráò yóò kọ̀ láti fetí sílẹ̀ sí ọ kí iṣẹ́ ìyanu mí le pọ̀ sí ní Éjíbítì.”
10. Mósè àti Árónì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí níwájú Fáráò, ṣùgbọ́n Olúwa sé ọkàn Fáráò le, òun kò sí jẹ́ kí àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni orílẹ̀ èdè rẹ̀.