6. Wọn yóò kún gbogbo ilé rẹ àti ilé àwọn ìjòyè rẹ àti ilé gbogbo àwọn ará Éjíbítì. Ohun ti baba rẹ tàbí baba baba rẹ kò tí ì rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ilẹ̀ náà títí di àkókò yìí.’ ” Nígbà náà ni Mósè pẹ̀yìndà kúrò níwájú Fáráò.
7. Àwọn ìjòyè Fáráò sọ fún “Yóò ti pẹ to tí ọkùnrin yìí yóò máa mú ìyọnu bá wa? Jẹ́ kí àwọn ènìyàn yìí lọ, kí wọn kí ó le sìn Olúwa Ọlọ́run wọn. Ṣe ìwọ kò ṣe àkíyèsí ṣíbẹ̀ pé, ilẹ̀ Éjíbítì ti parun tán?”
8. Nígbà náà ni a mú Árónì àti Mósè padà wá sí iwájú Fáráò ó sì wí fún wọn pé “Ẹ lọ sìn Olúwa Ọlọ́run yín. Ṣùgbọ́n àwọn ta ni nínú yín ni yóò ha lọ.”