Éfésù 2:3-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Nínú àwọn ẹni tí gbogbo wa pẹ̀lú ti wà rí nínú ìfẹ́kúfẹ ara wa, a ń mú ìfẹ́ ara àti ti inú ṣẹ, àti nípa ẹ̀dá àwa sì ti jẹ́ ọmọ ìbínú, gẹ́gẹ́ bí àwọn ìyókù pẹ̀lú.

4. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run, ẹni tí í ṣe ọlọ́rọ̀ ni àánú, nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó fi fẹ́ wa,

5. nígbà tí àwa tilẹ̀ ti kú nítorí ìrékọjá wa, ó sọ wá di ààyè pẹ̀lú Kírísítì oore ọ̀fẹ́ ni a ti fi gbà yín là.

Éfésù 2