21. Ẹ má gbọ̀n jìnnìjìnnì torí wọn, torí pé Olúwa Ọlọ́run yín tí ó wà láàrin yín, Ọlọ́run alágbára ni, àti Ọlọ́run tí ó tóbi lọ́pọ̀lọpọ̀.
22. Olúwa Ọlọ́run yín yóò lé gbogbo orílẹ̀ èdè wọ̀n-ọn-nì kúrò níwájú u yín díẹ̀díẹ̀. A kò ní gbà yín láàyè láti lé wọn dànù lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo. Kí àwọn ẹranko ìgbẹ́ má baà gbilẹ̀ sí i láàrin yín.
23. Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run yín yóò fi wọ́n lée yín lọ́wọ́, yóò sì máa fà wọ́n sínú un dàrúdàpọ̀ títí tí wọn yóò fi run.
24. Yóò fi àwọn ọba wọn lé e yín lọ́wọ́, ẹ̀yin ó sì pa orúkọ wọn rẹ́ lábẹ́ ọ̀run. Kò sí ẹni tí yóò lè dojú ìjà kọ yín títí tí ẹ ó fi pa wọ́n run.