1. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá mú u yín dé ilẹ̀ náà, tí ẹ ó wọ̀ lọ láti gbà, tí ó sì lé ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀ èdè kúrò níwájú u yín: Àwọn ará Hítì, Gígásì, Ámórì, Kénánì, Pérésì, Hífì àti àwọn ará Jébúsì: Àwọn orílẹ̀ èdè méje tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì pọ̀ jù yín lọ,
2. nígbà tí Olúwa Ọlọ́run yín bá sì ti fi wọ́n lé e yín lọ́wọ́, tí ẹ sì ti ṣẹ́gun wọn, kí ẹ pa wọ́n run pátapáta. Ẹ má ṣe bá wọn ṣe àdéhùn àlàáfíà, ẹ kò sì gbọdọ̀ sàánú un wọn.
3. Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ bá wọn dá àna. Àwọn ọmọbìnrin yín kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọkùnrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín,